Bá ò rẹ́ni fẹ̀hìntì…

'Joba Ojelabi
2 min readSep 4, 2022

Àkọlé àkọsilẹ yìí kò le ṣe àjèjì sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá tóotọ́. Ọrọ náà jáde láti inú ewì J.F Ọdúnjọ; ọ̀mọ̀wé tí ó kọ ìwé Aláwiye, “Iṣẹ́ lóògùn ìṣẹ́”. Ewì yìí kún fún ọpọlọpọ ọgbọ́n ṣùgbọ́n apá yìí ni o ń sọ sími lọ́kàn.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní a má n rò pé iṣẹ nìkan tó láti gbé ènìyàn dé ibi gíga. Àmọ́ njẹ́ ó wáa rí bẹ́ẹ̀ bí?

Àìmọye ìgbà ní a máa n rí àwọn ẹni tí n ṣiṣẹ́ lójú méjèèjì tí kò sì já mọ nkankan. Báa bá padà sí ọ̀rọ̀ Ọdúnjọ, a o rí wípé níwòn ìgbà tí iṣẹ ṣe kókó sí dídé ibi gíga, o ṣe pàtàkì kí a ní ẹni tí a le fèyìntì. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀mọ̀wé tí kọ́, “bí a kò bá rí ẹni fèyìntì, bí ọ̀lẹ làárí”.

Àmọ́ Ọdúnjọ tẹ̀síwájú nínú ọrọ rẹ̀, ó ní, “bí a kò bá rẹ́ni gbẹ́kẹ̀lẹ́, a tẹra mọ́ṣẹ́ ẹni…”. Èyí tó túmọ sí wípé tí èèyàn kò bá tíì rí ẹni gbọ́kànlé, o ṣe kókó láti múra sí iṣẹ́ ní ìrètí ọjọ ọ̀lá.

Máa dá ọrọ yìí dúró ní ibi yìí nítorí àwọn ọrẹ mí tí kò le kà Yorùbá. Amò yíò wùmí kí é ló tún gbé ewì Ọdúnjọ yìí yewo nítorí ọgbọn tí o kún inú rè.

--

--